1 Kings 12:1-19

Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí Rehoboamu

1 aRehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba. 2Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó wà ní Ejibiti síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Solomoni ọba, ó sì wà ní Ejibiti. 3Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jeroboamu, òun àti gbogbo ìjọ Israẹli sì lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n sì wí fún un pé: 4“Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”

5Rehoboamu sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.

6Nígbà náà ni Rehoboamu ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàgbà tí ń dúró níwájú Solomoni baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láààyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

7Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”

8Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín. 9Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?”

10Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. 11Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”

12Jeroboamu àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.” 13Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, 14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.” 15Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati láti ẹnu Ahijah ará Ṣilo ṣẹ.

16Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé:

Ìpín wo ni àwa ní nínú Dafidi,
ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jese?
Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Israẹli!
Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dafidi!
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli padà sí ilé wọn.
17Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé nínú ìlú Juda, Rehoboamu jẹ ọba lórí wọn síbẹ̀.

18Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu. 19Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dafidi títí di òní yìí.

Copyright information for YorBMYO